Lyrics

T'àwọn ile ni o wo, ni o wo, ni o wo, k'o to ṣe'un to fẹ ṣe, awe (to fẹ ṣe, awe) Àwọn ẹlẹtan ọrẹ wọn a ni ko ma ṣe lọ, àwọn nw'ẹhin rẹ o O ba dẹ wo ti baba, k'o wo ti yeye Wo t'àwọn to fẹràn rẹ tọkantọkan Mo ni, "Ko ro t'ẹni rẹ," jọwọ, ko ro ti t'ọla, ro t'ọjọ atisun to n bọ wa o T'ipilẹ ni o wo, ni o wo, ni o wo, k'o to ṣe'un to fẹ ṣe, awe (to fẹ ṣe, awe) Àwọn ẹgbẹ mọdaru wọn a yin ẹ, wọn a ma ni, "Aṣegbe ni t'oni o" O ba dẹ wo t'ọkàn rẹ, ah, wo t'ayọ rẹ Wo tibalẹ ọkàn to wun ọ o Mo ni, "Ko ro t'ẹni rẹ," jọwọ, ko ro ti t'ọla, ro t'ọjọ atisun to n bọ wa o Oju aye n wo ẹ, wọn n wo ẹ, jọwọ, rọra ṣe l'ode, awe (ṣe l'ode, awe) Abatẹnijẹ ọrẹ, wọn a tan ẹ, wọn a ma pe, "Ṣebí ìwọ lọga o" O ba dẹ f'ọgbọn ṣ'ẹgbọn o, f'ifura lo'gba La'na idunnu f'àwọn to n bọ lọna Mo ni, "Ko ro t'ẹni rẹ," jọwọ, ko ro ti t'ọla, ro t'ọjọ atisun to n bọ wa o Mo ni, "Ko wo ti baba o, wo ti yeye Wo t'àwọn to fẹràn rẹ tọkantọkan Mo ni, "Ko ro t'ẹni rẹ," jọwọ, ko ro ti t'ọla, ro t'ọjọ atisun to n bọ wa o T'àwọn ile ni o wo, ni o wo T'àwọn ile ni o wo, ni o wo T'àwọn ile ni o wo, ni o wo T'àwọn ile ni o wo, ni o wo
Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out