Lyrics

Ẹni ma ba wa ṣe pọ, ìyẹn a b'ẹwu ana sọnù A fi'wa tutu ṣ'aṣọ, a mọ tooto o Ẹni ma ba wa jẹun agba, a ko'wa ibajẹ sọnù A wa fọ'wọ rẹ, a mọ tooto o (tootoo-to o) Olofofo, ẹgbẹ àwọn ọdaluru Tẹmbẹlẹkun, awo ọlọtẹ o ni'ye Adanikanjẹ, alainitẹlọrun Wọn o ni le ba wa ṣe pọ Wọn o ni le ba wa rin pọ Wọn o ni le ba wa gbe pọ, rara Ẹni ma ba wa rin pọ, ìyẹn a ko'wa ìdọtí sọnù A gb'ẹsẹ s'ọna rere, a mọ tooto o Ẹni ma ba wa jẹun agba, a ko'wa ibajẹ sọnù A wa fọ'wọ rẹ, a mọ tooto o (tootoo-to o) Ṣọtẹṣebí, olopurọ ọbayejẹ Fibiṣẹwa, awo onibilisi Alaimọra, ẹgbẹ onímọdaru Wọn o ni le ba wa ṣe pọ Wọn o ni le ba wa rin pọ Wọn o ni le ba wa gbe pọ, rara Ẹni ma ba to pọ, ìyẹn a fi'wa ẹtẹ silẹ A wa tun'ra rẹ bi o, a mọ tooto o Ẹni ma ba wa jẹun agba, a ko'wa ibajẹ sọnù A wa fọ'wọ rẹ, a mọ tooto o (tootoo-to o) Ẹni ma ba wa ṣe pọ, ìyẹn a b'ẹwu ana sọnù A fi'wa tutu ṣ'aṣọ, a mọ tooto o Ẹni ma ba wa rin pọ, ìyẹn a ko'wa ìdọtí sọnù A gb'ẹsẹ s'ọna rere, a mọ tooto o Ẹni ma ba to pọ, ìyẹn a fi'wa ẹtẹ silẹ A wa tun'ra rẹ bi o, a mọ tooto o Ẹni ma ba wa jẹun agba, a ko'wa ibajẹ sọnù A wa fọ'wọ rẹ, a mọ tooto o (tootoo-to o)
Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out