Lyrics

Alagbawi mi onigbọwọ to yọ mi loko iya o Alagbawi mi onigbọwọ to yọ mi l'okun Modupe, ose, to san igbese mi Modupe, ose, to san gbese mi Iwo lo yo mi loko iya ti mo ko ori mi bo Àní iwo lo yomi ninu oko oshi ti mo kese mi bo Ose, modupe, to san igbese mi Ose oo, modupe, to san gbese mi Alagba wi mi (alagba wi mi) Onigbọwọ eda (onigbọwọ mi) Oseun, to san gbese mi (ose oo) Ọpẹ ni mo wa du nitemi (alagbawi mi, onigbọwọ mi o ṣeun to san igbese mi) Orun yo tori mi Mo d'ominira a tu mi silẹ Emi aji gbese ojosi Agbelebu tu mi sile oo Eleso ajeku, oti ko gba wole Eleso ajeku, oti ko igba wole (kogaba wole ko) Alagbawi mi, onigbọwọ mi Oseun to san gbese mi Alagbawi mi, onigbọwọ mi Oseun to san gbese mi Iyan ki s'ẹgbẹ isu laye Ma fo tolori we panduku Ibi isubu yato si ibi idide Ogba edeni lakoba ti wa A tun ipin ẹda yan lati ibi agbari A tori aye se ni calvary Agbelebu ibi ifese jin A ká iboju kuro aso ipọnju faya Alapa pe oniya ji oju re mo Ko je ni fi ni korogodo Alapa pe ti kogba wole Alagbawi mi (ose Olodumare) Onigbọwọ mi (alagbawi onigbọwọ mi) Ose, to san igbese mi (ose ooooo) Alagbawi wi mi (alagbawi mi) Onigbọwọ mi (onigbọwọ eda) Ose, to san igbese mi Akọsilẹ gbese ti parẹ Kosi wulo afi jo ko mo Ajigbese bo logun a sin gba Ẹjẹ ra jí gbese ateni dogo Eniti a dẹni tin fonka Eku ibanuje wa di erin Ajigbese ati adogo a ti bo Igi ti da okun ti ja Awa ti yọ Eni to wo igi ohun lo ri iye Ominira ti de Alagbawi mi (ata dogo) Onigbọwọ mi (atoni gbese) Ose, to san gbese mi (ata ji gbese awa mẹtẹta) Alagbawi mi (la ba bo loko iya o) Onigbọwọ mi (laba bo loko eru) Ose, to san gbese mi (opelope onigbọwọ alagbawi eda oo) Ọpẹ onife alailẹgbẹ F'ogo folugbala t'ojoko nite anu Ọpẹ alagbawi igbọwọ eda oo Owaye wa fi iku agbekorun mi tẹlẹ jona O ko mi ni la iya to ni Kọla aye o le ko o Emi mimo wa di ogun ibi si iye fún emi Mo d'ominira ah ah mo do mo Mo d'ominira eh eh moyege Baba mi lo laye at'ọrun, mo d'ominira Mo d'ominira eh eh, moyege Mo d'ominira ah ah, mo d'omo (mo di ọmọ lat'oni lọ) Mo d'ominira eh eh, mo yege (sha rẹni to sọbẹ pẹlu emi) Mo d'ominira ah ah, mo d'omo (bẹẹni ọmọ ni mi) Mo d'ominira eh eh, mo yege (kò sí gbese lọrùn mi ẹjẹ lo san gbogbo rẹ) Jesu san gbese mi tan, mo bọ lọwọ aninilara Alagbawi san tan mo dẹni aponle mo d'omo, mo d'omo mo d'ominira oooo Mo yege mo jo'gun aye raye (mo jo'gun aye raye iye ni temi) Mo d'omo, mo d'omo, mo d'ominira oooo Mo yege, mo jo'gun aye raye Mo d'ominira ah ah, mo d'omo Mo d'ominira eh eh, moyege (alagbawi lo sa sepe Ise Aye mi) Mo d'ominira ah ah, mo d'omo (onigbọwọ ohun lo sa sepe Ise mi o) Mo d'ominira eh eh, mo yege (ko sí wulo afi jogo mo o)
Writer(s): Tope Alabi Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out