Similar Songs
Lyrics
[Chorus]
Mimọ ni Ọ, mimọ ni Ọ, mimọ
Mimọ ni Ọ, mimọ ni Ọ, mimọ
[Verse 1]
Oluwa Ọlọrun Eledumare t'O pọ n'ipa ati agbara
Mimọ ni Ọ mimọ ni Ọ o mimọ
Gbogbo iṣẹda n sọ bẹẹ emi naa mo sọ bẹẹ
Lati ọgbun ẹmi i mi mo juba Rẹ
Mo juba Rẹ Ọba mimọ
Mo wolẹ fun Ọ Baba
Mo wolẹ fun Ọba toto
Lẹyin Rẹ
Lẹyin Rẹ, ko si o
Iwọ nikan, Iwọ nikan, Iwọ nikan
[Verse 2]
Mo juba rẹ Oluwa
Ọba to jokoo sori itẹ
Ọba to wa lori obiri aye maa ṣọla rẹ lọ
Mo wolẹ fun Ọ Ọba toto
Lẹyin Rẹ
Lẹyin Rẹ, ko si o
Iwọ t'O wa n'ipẹkun imọlẹ, Iwọ ni ipẹkun ọla, Iwọ ni ipẹkun agabara
[Verse 3]
Mo wari fun Ọ Ọlọla
Pẹlu iwariri lati ọgbun ẹmi mi
Imole to n tan sinu ookun mi ogo f'ooko Rẹ
Lẹyin Re Oluwa o
Lẹyin Rẹ o, ko si o
Olugbemiro, Oluṣaanumi, Olugbamila, Olugbamile, Oluwa
Lẹyin Rẹ o
Lẹyin Rẹ o, Baba ko si o
Tani i ba sin bi ko se eni to gba mi la?
Ẹni ti mi o ri ṣugbọn ti mo riṣẹ ọwọ Rẹ ninu aye mi
[Chorus]
Mimọ ni Ọ, mimọ ni Ọ o, mimọ
Aye ati ọrun nsọrọ ogo Re a n f'iṣẹ ọwọ Rẹ han, Iwọ, mimọ
Mo da ohun mi pọ mọ gbogbo iṣẹ Rẹ, emi, ẹmi mi ati eemi mi a n yin Ọ nigba gbogbo
Ọba to wa n'ipẹkun ọla, ipẹkun ogo, ipẹkun agbara, ipẹkun ẹwa Iwọ ni Oluwa
[Verse 4]
Pipe naa lo jẹ Oluwa
Pipe ni Ọ, pipe ni Ọ o, pipe
Ta lo le yọ kuro ninu Rẹ nigba ta o ti ẹ mọ
Pipe ni Ọ, pipe ni Ọ o, pipe
Yiyẹ ni Ọ
Yiyẹ ni Ọ, yiyẹ ni Ọ, yiyẹ
Ọdọ aguntan to joke sori itẹ o
Yiyẹ ni Ọ, yiyẹ ni Ọ, yiyẹ
[Verse 5]
Tito ni Ọ Ẹlẹdaa gbogbo iṣẹda
Olutọju gbogbo eniyan, Ọlọrun gbogbo ẹran ara
Ẹni ti n gbọ adura ọdọ Rẹ la n wa, Iwọ ni
Tito ni Ọ, tito ni Ọ, tito
[Verse 6]
Gigun ni Ọba to jokoo sori itẹ o
Gigun ni Ọ, gigun ni Ọ, gigun
O fi aye sọlẹ sori awọn isan omi, aye o le ri lailai ko le ri, iṣẹ Rẹ ni
[Verse 7]
Mo juba Rẹ, Ọba mimọ
Olori ẹgbẹẹgbẹrun ogun awọn angẹli, Iwọ ni
Mo wolẹ
Lẹyin Rẹ
Lẹyin Rẹ, ko si o
Iwọ nikan, Iwọ, Ọlọrun gbogbo araye
[Verse 8]
Mo wari fun Ọ Ọlọla
Pẹlu iwariri lati ọgbun ẹmi mi
Imọlẹ to n tan sinu ookun mi ogo f'ooko Rẹ
Lẹyin Rẹ (Lẹyin Rẹ)
Oluwa, Ọlọrun, Eledumare to pọ nipa ati agbara
Iwọ nikan ni Ọba, Iwọ nikan, Iwọ nikan, Iwọ nikan, Iwọ nikan
Ọlọrun gbogbo araye, ọdọ Rẹ ni ti gbogbo ẹran ara yoo wa ogo ni fun orukọ Rẹ lati ọgbun ẹmi mi
Iṣeda mi yin Ọ
Alaanu iṣẹda mi, alaanu aye mi, imọlẹ to tan sinu okunkun mi
Iwọ nikan, Olugbamilẹ, Olugbamila, Alaanu mi, Oluranlọwọ mi, Oluṣaan mi, Alaabo lori aye mi
Ẹni to fun mi lẹbun
Ẹni to fẹbun ṣe iṣẹda mi lọṣọọ
O logo de ẹbun mi lade, O fi ogo de ẹbun mi lade
Mo dupẹ mo yin Ẹ lati ọgbun ẹmi mi
Iwọ nikan ni Ọba
Written by: Sola Allyson