Lyrics

Ikoko akufo, o d'ero akitan o Ikoko to fo o, o ti dero akitan o Monomono ya lu'gi, oro wo 'nu ilu o Itiju bi aso akisa lo ma ri o O d'oro agbagba o, o d'eru f'ologbon O d'owo awon agba o, o d'eru f'ologbon Ilu Orita o Ilu alaafia Mo ni t'e ba de'be E ba mi ki won o Gbogbo wa la o f'ayo de 'le Gbogbo wa la o f'ayo de 'le wa Mo ni t'e ba ri o E ba nki Awero yen o Omoge awelewa to nda ni l'orun o Ile owo ni o wo s'aya Ile ola ni o wo s'aya o Seb'ade ori oko ni won Obinrin to n'iwa t'o l'ewa Iwuri obi ni won o ma je Mobinrin to gb'eko to mu lo Ori re dara, ori re sunwon, o d'adufe olori oko Ori re dara, ori re sunwon, o d'abefe o Ikoko to fo i s'oun a mu se'be Ikoko to fo i s'oun a mu to'le Ikoko to fo i s'oun a mu r'odo Ikoko to fo i s'oun a mu yan'gan Ibadi aran d'eni a mu se yeye o Bi eye ti o l'apa Ibadi aran d'eni a mu se yeye o O ba ma i lo o O ba ma i lo o Duro se'un obinrin nse O ba ma i lo o Awero o ba ma i lo o Gb'aye se'un obinrin nse O ba duro f'inu sh'oyun Duro se'un obinrin nse O ba gb'aye feyin gbomopon Gb'aye se'un obinrin nse O ba ma i lo o O ba ma i lo o Duro se'un obinrin nse Ilu Orita o Ilu alaafia Mo ni t'e ba de'be E ba mi ki won o Gbogbo wa la o f'ayo de 'le Gbogbo wa la o f'ayo de 'le wa Mo ni t'e ba ri o E ba nki Awero yen o Omoge awelewa to nda ni l'orun o Ile owo ni o wo s'aya Ile ola ni o wo s'aya o
Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out