Paroles

Gbé mi ṣán lẹ̀ Kó mi sí'ta Fàmí lẹwù ya Tẹ̀ mí lọ́rùn pa Ènìyàn lásán ni mo jẹ́ Mo fúyẹ́ bíi paper Ìjí jà lódò Ó gbé mi lọ sóko Ẹ̀dùn ọkàn oun l'ọkọ̀ Gbé mi lọ síbi tó kàn Ọ̀gá tà, ọ̀gá ò tà Ọlọọpá gba rìbá kàsà Ẹ̀dùn ọkàn oun l'ọkọ̀ Gbé mi lọ ibi mò ń lọ Ẹ̀dùn ọkàn fún mi lọ́kàn Ọkùnrin mẹ́ta dé'bi tí mò ń lọ Èmi ni ìmọ́lẹ̀ O ló'kùnkùn wọ gbó lọ Mo fà á lẹ́'wù ya Mo tẹ̀ l'ọ́rùn pa Ènìyàn lásán mi ò jẹ́ Mo wíwo bí ẹ̀san Èmi ni ìjì tó jà l'ódò Tó gb'ọba wọn lọ s'óko Ẹ̀dùn ọkàn oun l'ọkọ̀ Gbé mi lọ síbi tó kàn Ọ̀gá tà, ọ̀gá ò tà Ọlọpa gba rìbá kàsà Ẹ̀dùn ọkàn oun l'ọkọ̀ Gbé mi lọ ibi mò ń lọ Ẹ̀dùn ọkàn fún mi lọ́kàn Ọkùnrin mẹ́ta dé'bi tí mò ń lọ Ẹ̀dùn ọkàn oun l'ọkọ̀ Gbé mi lọ síbi tó kàn Ọ̀gá tà, ọ̀gá ò tà Ọkùnrin mẹ́ta dé'bi tí mò n lọ
Writer(s): Olawale Olofo'ro Lyrics powered by www.musixmatch.com
instagramSharePathic_arrow_out