Top Songs By K1 De Ultimate
Similar Songs
Credits
AUSFÜHRENDE KÜNSTLER:INNEN
K1 De Ultimate
Künstler:in
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Schlagzeug
KOMPOSITION UND LIEDTEXT
Olasunkanmi Ayinde Marshal
Songwriter:in
Lyrics
Ìwà lẹwà ọmọ ènìyàn
(Ò bá dákun tọ́jú ìwà ẹ)
Ìwà ọmọ ní ń m’ọ́mọ ṣ’òkígbẹ́
Baàmi Àkànní Rasaki mi o
Àwọn èèyàn pàtàkì pàtàkì
Gbogbo wọn ń ba Ọlọ́hun Ọba dúpẹ́
Wọ́n ń dúpẹ́ fún Ọlọ́hun Ọba
Lórí ìṣẹ̀míi yín fún ọjọ́ọ̀bí eléyìí o
Lára àwọn ni His Excellency General Ike Nwanchuku
Wọ́n ní kí n ba yín dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́hun sati Ọba
Wọ́n ń ba yín dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba
Wọ́n ní Ọlọ́hun Ọba ló lè ṣé o èèyàn kọ́
Ìyẹn ni a ṣe ń f’ògo hàn sí Ọlọ́hun
Oore tó ṣe fún ẹ lórí i yín lójoojúmọ́
A wá ń bẹ̀ ẹ́ o Ọlọ́hun Sati mi o
Lórí Rasaki mi Àkànní
Ẹyin lójú l’Àkànní adé jẹ́ fún gbogbo wa
Là ń rá bàbà síwájú Ọlọ́hun wí pé kó da yín sí
Ká a ri yín pẹ́ Àkànní Rasaki mi o ìwà ni
Kábíèsí Ọba Adéwálé Adédàpọ̀ Ọba Tẹ́júọshọ́
Wọ́n ní kí n ki yín
Wọ́n ní ẹ kú oríire
Àwa tá a péjú eléyìí o, a tún jọ máa ṣe tóńbọ̀ ni Àkànní Rasaki mi
Gbogbo àwọn olorì ayaba t’òkè ọnà wọ́n ní kí n ki yín
Gbogbo Ọba ládé ládé
Wọ́n ní n ki yín
Wọ́n ní ẹ ṣe ọdún eléyìí o
Ẹ̀ ẹ́ ṣ’ẹ̀míì Àyìndé Olúgbọ́n asáakin
Àrè pagidìda sọ’gi di ọmọ ènìyàn
Ọkọ ọmọba Adéṣọlá, Ṣọlá baby ọmọ bàbá Làgbámú
Ọmọ Ọba ni Ṣọlá
Ìbá ṣe pé ọmọbìnrin ń jọba lórí orí ìtẹ́ o
A à bá gbádé fún Ṣọlá
Ṣùgbọ́n bàbá tó bi lọ́mọ ó ṣì ń bẹ láyé Prince Samuel mi ọmọ Adédoyin
Bàbá gangan fún’ra ẹ̀
Ìwà ọmọ ní n m’ọ́mọ ṣe òkígbẹ́
Ẹ tọ́jú ẹ̀ dada
Ìwà lolúwa ń wò, ò bá dákun tọ́jú ẹ̀ dada
Ìwà yìí ló ṣòwo
Ló ṣe ohun gbogbo ní mèremère ò bá dákun tọ́jú ẹ̀ dada
Ìwà loníwà mí wò bí ò bá ti ṣí anybody mọ́
Baàmi Àkànní, ìwà ṣe pàtàkì pàtàkì
Àdélébáre Àdélébáre Àdélébáre Àdélébáre
Àdélébáre Àrìnàkore Àkòyà ibi ìwà ẹni ni
Àkànní oníwà ló nìwà o
Ìwà ọmọ ní n m’ọ́mọ ṣe òkígbẹ́
Ò bá dákun tọ́jú ẹ̀ dadada
Ìwà lẹwà ọmọ ènìyàn (ò bá dákun tọ́jú ìwà ẹ )
Ìwà lẹwà ọmọ ènìyàn (ò bá dákun tọ́jú ìwà ẹ )
Arábámbí ń jayé ọba o
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Arábámbí ń jayé ọba o
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Baàmi Àkànní, àrábámbí ń jayé ọba o
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Àkànní adé ń jayé Ọba
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Ẹ kí Olúkòṣo àyánrán iná
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Ẹ bá mi kí Olúkòso àyánrán iná
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Abirin pípọn f’ọmọ lójú ọkọ Ọya
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Awàláòjí Ọbakòso
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Omi Àjànàkú o má fiyọ̀ si
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Ẹ kooo
Ẹ kooo
Ẹ kooo
Ẹ kooo
Ẹ k’ólúkòso àyánrán iná
(Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó)
Ọmọ onílé ajé là ń kí
(Ààrẹ gangan Àkànní)
Ọmọ onílé ajé là ń kí
(Ààrẹ gangan Àkànní)
Ọ̀rẹ́ Sàámú Adédoyin
Sàámú Adédoyin
Sàámú Adédoyin
Kiní tó o pé ó bùn mi ńkọ́?
(À bó ò ní bùn mí mọ́)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi)
Ọ ṣá mọ̀ pé ǹ lẹ́nìkan
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùnmi)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùnmi)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùnmi)
Kiní tó o pé ó bùn mi ńkọ́?
(À bó ò ní bùn mí mọ́)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi)
Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi)
Ọ ṣá mọ̀ pé ǹ lẹ́nìkan
Onílé ajé là ń kí
(Ààrẹ gangan Àkànní)
Ọ̀rẹ́ sàámú Adédoyin
Ọ̀rẹ́ sàámú Adédoyin
Ọ̀rẹ́ sàámú Adédoyin
Ọ̀rẹ́ sàámú Adédoyin
Àmín o ọmọ ni ó jogún rẹ (Àmín o)
Àkànní ọmọ ni ó jogún ẹ (Àmín o)
Mo damọ̀ ni mo ṣe ń kọ Àyìndé
Onílé ajé Ọkọ́ya Àkànní Rasaki
Happy 85 Birthday márùnlélógúnmẹ́rin Àkànní adé
Baàmi nínú ọlá ńlá
Ọkọ Adija kubura Oritókẹ́
Àkànní ọkọ Noimotu mi
Àna Ọláńrewájú mi ọmọ Tẹ́júọshó
Senate máa wolẹ̀ Láńrewájú
Àkànní Ọkọ́ya onílé ajé
Eleganza Ọkọ́ya Àkànní
Eleganza Ọkọ́ya Àkànní
Bí n bá f’ojú kan Ọkọ́ya Àkànní Rasaki
Wọn kì í dá’ni lé òfo Bíọ́dún dé
Kẹ r’ọ̀dọ̀ Rasaki o ọmọ onílé ajé mi
Àkànní Ọkọ́ya tó ń jẹ́ Eleganza
Mo mọ̀’wọ̀n ara mi
(Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ)
Àkànní Onílé ajé
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
(Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ)
(Ayé ni n ó jẹ mi ò ní jìyà)
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
(Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ)
Àkànní onílé ajé
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
(Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ)
Ọmọ onílé ajé
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
(Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ)
(Ayé ni n ó jẹ mi ò ní jìyà)
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
(Ayé ni n ó jẹ mi ò ní jìyà)
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
Ọkọ ti ìdùnnú Ọkọ́ya Noimotu
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
(Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ)
Noimo òun ni Baby Ọkọ́ya tì ẹ́ yàtọ̀
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
(Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ)
Áńgẹ́lì Àkànní Ọkọ́ya Noimotu
(Mo mọ̀’wọ̀n ara mi)
(Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ)
Àkànní Rasaki mi
A dúpẹ́ fún Ọlọ́hun Ọba
B’Ọ́lọ́hun Ọba ṣe ṣe Ọlá
Aliko máa wolẹ̀ ọmọ Dangote
Séríkí Me’rice Séríkí Me’Sugar Séríkí Me’diesel Séríkí Me’oil
Ali máa wolẹ̀ Aliko máa wolẹ̀ o máa rọra
O mà kú àdúrótì Àkànní Rasaki mi
Onílé ajé baàmi Rasaki mi Àkànní
Nínú àlàáfíà ká ri yín pẹ́
Nínú ẹ̀mí gígùn ọlá ńlá
Governor Babájídé ọmọ Sanwoolú
Ó ní kí n ki yín lorúkọ Aṣíwájú
Àkànbí Olódó idẹ
Wọ́n ní kí n ki yín Àkànní nínú àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn
Ẹ ẹ́ ṣe ọ̀pọ̀ ọdún láyé
Ọlọ́hun Ọba o atẹ̀lénimáyà ni ẹ́
O mọ b’ó ti ṣe ń ṣe sọ́wọ́ ẹrú ẹ̀ tó dá
Òun ló ń bá mi ṣọ ẹ́ Rasaki mi Àkànní
Àkànní onílé ajé Eleganza mi Àkànní
Ọkọ Adija Kubura mi
Àna ti Sule Shadow mi Rasaki Àkànní
Ọkọ Noimotu mi òyìnbó Ọkọ́ya Noimotu mi òyìnbó
Àkànní o ò ní rí’hun tó jù yín lọ
Bó wọlá Muhammadu o
Ṣùgbọ́n nítorí èmi kọ́ o (nítorí Muhammadu o)
Written by: Olasunkanmi Ayinde Marshal